Nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ara gbogbo eniyan ìlú Jerusalẹmu náà kò sì balẹ̀. Ọba bá pe gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin láàrin àwọn eniyan, ó wádìí nípa ibi tí a óo ti bí Kristi lọ́wọ́ wọn. Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé. ‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda, o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda. Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde, tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ” Hẹrọdu bá pe àwọn amòye náà síkọ̀kọ̀, ó fọgbọ́n wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà yọ lọ́dọ̀ wọn. Ó bá rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó ní, “Ẹ lọ, kí ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ọmọ náà. Nígbà tí ẹ bá rí i, ẹ wá ròyìn fún mi kí èmi náà lè lọ júbà rẹ̀.”
Kà MATIU 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 2:3-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò