Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn.
Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.”
Josẹfu bá dìde ní òru, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.”
Nígbà tí Hẹrọdu rí i pé àwọn amòye tan òun jẹ ni, inú bí i pupọ. Ó bá pàṣẹ pé kí wọn máa pa gbogbo àwọn ọmọ-ọwọ́ lọkunrin ní Bẹtilẹhẹmu ati ní gbogbo agbègbè ibẹ̀ láti ọmọ ọdún meji wálẹ̀ títí di ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó fọgbọ́n wádìí lọ́wọ́ àwọn amòye.
Èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Jeremaya sọ lè ṣẹ pé,
“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,
ẹkún ati ọ̀fọ̀ gidi.
Rakẹli ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀;
ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀,
nítorí wọn kò sí mọ́.”
Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti. Ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ́, kí o pada lọ sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọmọ náà ti kú.” Josẹfu bá dìde, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀ pada sí ilẹ̀ Israẹli.
Nígbà tí Josẹfu gbọ́ pé Akelau ni ó jọba ní Judia ní ipò Hẹrọdu baba rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ sibẹ. Lẹ́yìn tí a ti kìlọ̀ fún un lójú àlá, ó yẹra níbẹ̀ lọ sí agbègbè Galili. Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”