MATIU 18:21-35

MATIU 18:21-35 YCE

Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?” Jesu dá a lóhùn pé, “N kò sọ fún ọ pé ìgbà meje; ṣugbọn kí ó tó ìgbà meje lọ́nà aadọrin! Nítorí pé ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ yanjú owó òwò pẹlu àwọn ẹrú rẹ̀. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣírò owó, wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọ̀kẹ́ àìmọye. Kò ní ohun tí yóo fi san gbèsè yìí, nítorí náà olówó rẹ̀ pàṣẹ pé kí á ta òun ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ní, kí á fi san gbèsè rẹ̀. Ẹrú náà bá dọ̀bálẹ̀, ó bẹ olówó rẹ̀ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san gbogbo gbèsè mi fún ọ.’ Olówó rẹ̀ wá ṣàánú rẹ̀, ó bá dá a sílẹ̀, ó sì bùn ún ní owó tí ó yá. “Nígbà tí ẹrú náà jáde, ó rí ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ ẹ́ ní eélòó kan. Ó bá dì í mú, ó fún un lọ́rùn, ó ní; ‘San gbèsè tí o jẹ mí.’ Ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá dọ̀bálẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san án fún ọ.’ Ṣugbọn kò gbà; ẹ̀wọ̀n ni ó ní kí wọ́n lọ jù ú sí títí yóo fi san gbèsè tí ó jẹ. Nígbà tí àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn pupọ, wọ́n bá lọ ro ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún olówó wọn. Olówó ẹrú náà bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Ìwọ ẹrú burúkú yìí! Mo bùn ọ́ ní adúrú gbèsè nnì nítorí o bẹ̀ mí. Kò ha yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ, bí mo ti ṣàánú rẹ?’ Inú bí olówó rẹ̀, ó bá fà á fún ọ̀gá àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n títí yóo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ tán. “Bẹ́ẹ̀ ni Baba mi ọ̀run yóo ṣe si yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kò bá fi tọkàntọkàn dáríjì arakunrin rẹ̀.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú MATIU 18:21-35