MATIU 17:10-27

MATIU 17:10-27 YCE

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í pé, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́kọ́ dé?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Òtítọ́ ni pé Elija yóo wá, yóo sì mú ohun gbogbo bọ̀ sípò. Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.” Ó yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà náà pé nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó ń sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan, ọkunrin kan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ní, “Alàgbà, ṣàánú ọmọ mi, nítorí wárápá a máa gbé e, a sì máa joró pupọ. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà, a máa ṣubú lu iná; ní ọpọlọpọ ìgbà ẹ̀wẹ̀, a máa ṣubú sinu omi. Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣugbọn wọn kò lè wò ó sàn.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.” Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà. Nígbà tí ó yá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu níkọ̀kọ̀, wọn bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Nítorí igbagbọ yín tí ó kéré ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹ bá ní igbagbọ tí kò ju wóró musitadi tí ó kéré pupọ lọ, tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbẹ̀,’ yóo sì kúrò. Kó ní sí ohun kan tí ẹ kò ní lè ṣe. [ Irú ẹ̀mí burúkú báyìí kò lè jáde àfi nípa adura ati ààwẹ̀.”] Nígbà tí wọ́n péjọ ní Galili Jesu sọ fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á; a óo sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.” Ọ̀rọ̀ yìí bà wọ́n ninu jẹ́ pupọ. Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, àwọn tí ń gba owó Tẹmpili lọ sí ọ̀dọ̀ Peteru, wọ́n bi í pé, “Ṣé olùkọ́ni yín kì í san owó Tẹmpili ni?” Ó ní, “Kí ló dé? A máa san án.” Nígbà tí ó dé ilé, Jesu ló ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ni o rò, Simoni? Lọ́wọ́ àwọn ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó-orí tabi owó-odè? Lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ ni tabi lọ́wọ́ àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àlejò ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “Èyí ni pé kò kan àwọn ọmọ onílẹ̀. Sibẹ kí á má baà jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún wọn, lọ sí etí òkun, ju ìwọ̀ sí omi; ẹja kinni tí o bá fà sókè, mú un, ya ẹnu rẹ̀, o óo rí owó fadaka kan níbẹ̀. Mú un kí o fi fún wọ́n fún owó tèmi ati tìrẹ.”

Àwọn fídíò fún MATIU 17:10-27