Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí? Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi? Gbogbo àwọn arabinrin rẹ̀ kọ́ ni wọ́n wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín? Níbo ni ó wá ti rí gbogbo nǹkan wọnyi?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́. Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì àfi ní ìlú baba rẹ̀ ati ní ilé rẹ̀.” Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ níbẹ̀ nítorí wọn kò ní igbagbọ.
Kà MATIU 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 13:54-58
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò