Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀. Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni. Salimoni bí Boasi, ìyá Boasi ni Rahabu, Boasi bí Obedi. Ìyá Obedi ni Rutu. Obedi bí Jese. Jese bí Dafidi ọba. Dafidi bí Solomoni. Aya Uraya tẹ́lẹ̀ ni ìyá Solomoni. Solomoni bí Rehoboamu, Rehoboamu bí Abija, Abija bí Asa. Asa bí Jehoṣafati, Jehoṣafati bí Joramu, Joramu bí Usaya. Usaya bí Jotamu, Jotamu bí Ahasi, Ahasi bí Hesekaya. Hesekaya bí Manase, Manase bí Amosi, Amosi bí Josaya. Josaya bí Jekonaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ní àkókò tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni. Lẹ́yìn tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni, Jekonaya bí Ṣealitieli, Ṣealitieli bí Serubabeli. Serubabeli bí Abihudi, Abihudi bí Eliakimu, Eliakimu bí Asori. Asori bí Sadoku, Sadoku bí Akimu, Akimu bí Eliudi. Eliudi bí Eleasari, Eleasari bí Matani, Matani bí Jakọbu. Jakọbu bí Josẹfu ọkọ Maria, ẹni tí ó bí Jesu tí à ń pè ní Kristi.
Kà MATIU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 1:2-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò