OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí pé èmi OLUWA kì í yipada, ni a kò fi tíì run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu patapata. Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín. Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Báwo ni a ti ṣe lè yipada?’ Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe fún eniyan láti ja Ọlọrun lólè? Ṣugbọn ẹ̀ ń jà mí lólè. Ẹ sì ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni à ń gbà jà ọ́ lólè?’ Nípa ìdámẹ́wàá ati ọrẹ yín ni. Ègún wà lórí gbogbo yín nítorí pé gbogbo orílẹ̀-èdè yín ní ń jà mí lólè. Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á. N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Kà MALAKI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MALAKI 3:6-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò