Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á. N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Kà MALAKI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MALAKI 3:10-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò