LUKU 9:37-62

LUKU 9:37-62 YCE

Ní ọjọ́ keji, lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ eniyan wá pàdé rẹ̀. Ọkunrin kan ninu àwùjọ kígbe pé, “Olùkọ́ni, mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú ọmọ mi, nítorí òun nìkan ni mo bí. Ẹ̀mí kan a máa gbé e. Lójijì yóo kígbe tòò, ara rẹ̀ óo le gbandi. Yóo bá máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, ni ẹ̀mí yìí yóo bá gbé e ṣánlẹ̀; kò sì ní tètè fi í sílẹ̀. Mo bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.” Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun. Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi wọ̀ yín létí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́.” Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí. Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn. Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.” Johanu sọ fún un pé, “Ọ̀gá, a rí ẹnìkan tí ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. A fẹ́ dá a lẹ́kun nítorí kì í ṣe ara wa.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.” Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu. Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é. Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé o fẹ́ kí á pe iná láti ọ̀run kí ó jó wọn pa?” Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí. Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “N óo máa bá ọ lọ sí ibikíbi tí o bá ń lọ.” Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.” Ó bá sọ fún ẹlòmíràn pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ṣugbọn onítọ̀hún dáhùn pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn. Ìwọ ní tìrẹ, wá máa waasu ìjọba Ọlọrun.” Ẹlòmíràn tún sọ fún un pé, “N óo tẹ̀lé ọ Oluwa. Ṣugbọn jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.” Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Kò sí ẹni tí ó bá ti dá ọwọ́ lé lílo ẹ̀rọ-ìroko, tí ó bá tún ń wo ẹ̀yìn tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọrun.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ