LUKU 6:39-49

LUKU 6:39-49 YCE

Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn. Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Ṣugbọn bí ọmọ-ẹ̀yìn bá jáfáfá yóo dàbí olùkọ́ rẹ̀. “Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi ńlá tí ó wà lójú ìwọ alára? Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ. “Igi rere kò lè so èso burúkú. Bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lé so èso rere. Èso tí igi kan bá so ni a óo fi mọ̀ ọ́n. Nítorí eniyan kò lè ká èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹlẹ́gùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò lè rí èso ọsàn lórí igi ọdán. Eniyan rere ń mú ohun rere wá láti inú orísun rere ọkàn rẹ̀. Eniyan burúkú ń mú nǹkan burúkú jáde láti inú ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí ohun tí ó bá wà ninu ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni ń sọ jáde. “Kí ló dé tí ẹ̀ ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa,’ tí ẹ kì í ṣe ohun tí mo sọ? Ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó ń ṣe é, n óo sọ fun yín ẹni tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jọ. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé, tí ó wa ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ó jìn, tí ó wá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé orí àpáta. Nígbà tí ìkún omi dé, tí àgbàrá bì lu ilé náà, kò lè mì ín, nítorí wọ́n kọ́ ọ dáradára. Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò ṣe é, ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé kalẹ̀ láì ní ìpìlẹ̀. Nígbà tí àgbàrá bì lù ú, lẹsẹkẹsẹ ni ó wó, ó sì wó kanlẹ̀ patapata.”

Àwọn fídíò fún LUKU 6:39-49