LUKU 6:27-38

LUKU 6:27-38 YCE

“Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín. Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ yín, ẹ fún un. Bí ẹnìkan bá mú nǹkan yín, ẹ má bèèrè rẹ̀ pada. Bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan máa ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣe sí wọn. “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú. Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú. “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín. Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.”

Verse Images for LUKU 6:27-38

LUKU 6:27-38 - “Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín. Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ yín, ẹ fún un. Bí ẹnìkan bá mú nǹkan yín, ẹ má bèèrè rẹ̀ pada. Bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan máa ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.
“Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú. Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.


“Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín. Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.”LUKU 6:27-38 - “Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín. Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ yín, ẹ fún un. Bí ẹnìkan bá mú nǹkan yín, ẹ má bèèrè rẹ̀ pada. Bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan máa ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.
“Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú. Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.


“Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín. Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.”