LUKU 23:1-25

LUKU 23:1-25 YCE

Ni gbogbo àwùjọ bá dìde, wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án pé, “A rí i pé ńṣe ni ọkunrin yìí ń ba ìlú jẹ́. Ó ní kí àwọn eniyan má san owó-orí. Ó tún pe ara rẹ̀ ní Mesaya, Ọba.” Pilatu bá bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Ó dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí i.” Pilatu wá sọ fún àwọn olórí alufaa ati àwọn eniyan pé, “Èmi kò rí àìdára kan tí ọkunrin yìí ṣe.” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ tẹnu mọ́ ẹ̀sùn wọn pé, “Ó ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ da àwọn eniyan rú; Galili ni ó ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ti dé gbogbo Judia níhìn-ín nisinsinyii.” Nígbà tí Pilatu gbọ́ èyí, ó bèèrè bí ará Galili bá ni Jesu. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé lábẹ́ àṣẹ Hẹrọdu ni ó wà, ó rán an sí Hẹrọdu, nítorí pé Hẹrọdu náà kúkú wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà. Nígbà tí Hẹrọdu rí Jesu, inú rẹ̀ dùn pupọ. Nítorí ó ti pẹ́ tí ó ti fẹ́ rí i, nítorí ìró rẹ̀ tí ó ti ń gbọ́. Ó ń retí pé kí Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú òun. Ó bi Jesu ní ọpọlọpọ ìbéèrè ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn rárá. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin dúró níbẹ̀, wọ́n ń tẹnu mọ́ ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án. Hẹrọdu ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n gbé ẹ̀wù dáradára kan wọ̀ ọ́; Hẹrọdu bá tún fi ranṣẹ pada sí Pilatu. Ní ọjọ́ náà Hẹrọdu ati Pilatu di ọ̀rẹ́ ara wọn; nítorí tẹ́lẹ̀ rí ọ̀tá ni wọ́n ń bá ara wọn ṣe. Pilatu bá pe àwọn olórí alufaa, ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fa ọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ mi bí ẹni tí ó ń ba ìlú jẹ́. Lójú yín ni mo wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, tí n kò sì rí àìdára kan tí ó ṣe, ninu gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án. Hẹrọdu náà kò rí nǹkankan wí sí i, nítorí ńṣe ni ó tún dá a pada sí wa. Ó dájú pé ọkunrin yìí kò ṣe nǹkankan tí ó fi yẹ kí á dá a lẹ́bi ikú. Nítorí náà nígbà tí a bá ti nà án tán, n óo dá a sílẹ̀.” [ Nítorí ó níláti dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún wọn ní àkókò àjọ̀dún.] Ṣugbọn gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé, “Mú eléyìí lọ! Baraba ni kí o dá sílẹ̀ fún wa.” (Baraba ti dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú nígbà kan, ó sì paniyan, ni wọ́n fi sọ ọ́ sẹ́wọ̀n.) Pilatu tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu! Kàn án mọ́ agbelebu!” Ó tún bi wọ́n ní ẹẹkẹta pé, “Kí ni nǹkan burúkú tí ó ṣe? Èmi kò rí ìdí kankan tí ó fi jẹ̀bi ikú. Nígbà tí mo bá ti nà án tán n óo dá a sílẹ̀.” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ múra kankan, wọ́n ń kígbe pé kí ó kàn án mọ́ agbelebu. Ohùn wọn bá borí. Pilatu bá gbà láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́. Ó dá ẹni tí wọ́n ní àwọn fẹ́ sílẹ̀: ẹni tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí pé ó paniyan. Ó bá fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ