LUKU 19:1-27

LUKU 19:1-27 YCE

Nígbà tí Jesu dé Jẹriko, ó ń la ìlú náà kọjá. Ọkunrin kan wà tí ó ń jẹ́ Sakiu. Òun ni olórí agbowó-odè níbẹ̀. Ó sì lówó. Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni. Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá. Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.” Ni Sakiu bá sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á lálejò. Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!” Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.” Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà. Nítoí Ọmọ-Eniyan dé láti wá àwọn tí wọ́n sọnù kiri, ati láti gbà wọ́n là.” Bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọnyi, ó tún fi òwe kan bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àwọn eniyan sí rò pé ó tó àkókò tí ìjọba Ọlọrun yóo farahàn. Nítorí náà ó sọ fún wọn pé, “Ọkunrin ìjòyè pataki kan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n fẹ́ fi jọba níbẹ̀ kí ó sì pada wálé lẹ́yìn náà Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’ Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn! “Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ. Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’ Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’ “Ẹkẹta dé, ó ní, ‘Alàgbà, owó wúrà rẹ nìyí, aṣọ ni mo fi dì í, mo sì fi pamọ́, nítorí mo bẹ̀rù rẹ. Nítorí òǹrorò eniyan ni ọ́. Níbi tí o kò fi nǹkan sí ni o máa ń wá a sí; níbi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o ti máa ń kórè.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè. Kí ni kò jẹ́ kí o lọ fi owó mi pamọ́ sí banki, tí ó fi jẹ́ pé bí mo ti dé yìí, ǹ bá gbà á pẹlu èlé?’ “Ó bá sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó wúrà náà ní ọwọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní owó wúrà mẹ́wàá.’ Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’ Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní! Ní ti àwọn ọ̀tá mi wọnyi, àwọn tí kò fẹ́ kí n jọba, ẹ mú wọn wá síhìn-ín, kí ẹ pa wọ́n lójú mi!’ ”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ