Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí. Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’ Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan, ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ” Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí! Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?”
Kà LUKU 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: LUKU 18:2-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò