LUKU 12:13-31

LUKU 12:13-31 YCE

Ẹnìkan ninu àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, sọ fún arakunrin mi kí ó fún mi ní ogún tí ó kàn mí.” Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.” Jesu bá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ìkórè oko rẹ̀ pọ̀ pupọ. Ó wá ń rò ninu ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kí ni ǹ bá ṣe o, nítorí n kò rí ibi kó ìkórè oko mi pamọ́ sí?’ Ó ní, ‘Mo mọ ohun tí n óo ṣe! Ńṣe ni n óo wó àwọn abà mi. N óo wá kọ́ àwọn ńláńlá mìíràn; níbẹ̀ ni n óo kó àgbàdo mi sí ati àwọn ìkórè yòókù. N óo wá sọ fún ọkàn mi pé: ọkàn mi, o ní ọ̀pọ̀ irè-oko tí ó wà ní ìpamọ́ fún ọdún pupọ. Ìdẹ̀ra dé. Máa jẹ, máa mu, máa gbádùn!’ Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.” Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa páyà nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Nítorí ẹ̀mí ṣe pataki ju oúnjẹ lọ, ara sì ṣe pataki ju aṣọ lọ. Ẹ ṣe akiyesi àwọn ẹyẹ; wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè. Wọn kò ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà. Sibẹ Ọlọrun ń bọ́ wọn. Mélòó-mélòó ni ẹ fi sàn ju àwọn ẹyẹ lọ. Ta ni ninu yín tí ó lè páyà títí dé ibi pé yóo fi ẹsẹ̀ bàtà kan kún gíga rẹ̀? Nítorí náà, bí ẹ kò bá lè ṣe ohun tí ó kéré jùlọ, kí ló dé tí ẹ fi ń páyà nípa àwọn nǹkan yòókù? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu ọlá rẹ̀ kò wọ aṣọ tí ó dára tó wọn. Bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo fi aṣọ wọ̀ yín, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré yìí! “Nítorí náà, ẹ̀yin ẹ má máa páyà kiri nítorí ohun tí ẹ óo jẹ. (Nítorí pé irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn alaigbagbọ ayé yìí ń dààmú kiri sí.) Baba yín sá mọ̀ pé ẹ nílò wọn. Ṣugbọn kí ẹ máa kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni yóo fun yín pẹlu.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú LUKU 12:13-31