Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè. Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀. Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀.
“Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀! N óo fi ẹni tí ẹ̀ bá bẹ̀rù hàn yín. Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá pa ara tán, ó ní àṣẹ láti tún sọ eniyan sinu ọ̀run àpáàdì. Mo sọ fun yín, ẹ bẹ̀rù olúwarẹ̀.
“Mo ṣebí kọbọ meji ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ marun-un. Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí Ọlọrun fi ojú fò dá. Àní sẹ́, gbogbo irun orí yín ni ó níye. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.
“Mo sọ fun yín, gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan ni a óo sẹ́ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun.
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ-Eniyan, a óo dáríjì í. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò ní dáríjì í.
“Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóo kọ yín ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ ní àkókò náà.”
Ẹnìkan ninu àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, sọ fún arakunrin mi kí ó fún mi ní ogún tí ó kàn mí.”
Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.”
Jesu bá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ìkórè oko rẹ̀ pọ̀ pupọ. Ó wá ń rò ninu ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kí ni ǹ bá ṣe o, nítorí n kò rí ibi kó ìkórè oko mi pamọ́ sí?’ Ó ní, ‘Mo mọ ohun tí n óo ṣe! Ńṣe ni n óo wó àwọn abà mi. N óo wá kọ́ àwọn ńláńlá mìíràn; níbẹ̀ ni n óo kó àgbàdo mi sí ati àwọn ìkórè yòókù. N óo wá sọ fún ọkàn mi pé: ọkàn mi, o ní ọ̀pọ̀ irè-oko tí ó wà ní ìpamọ́ fún ọdún pupọ. Ìdẹ̀ra dé. Máa jẹ, máa mu, máa gbádùn!’ Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’
“Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.”
Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa páyà nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Nítorí ẹ̀mí ṣe pataki ju oúnjẹ lọ, ara sì ṣe pataki ju aṣọ lọ. Ẹ ṣe akiyesi àwọn ẹyẹ; wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè. Wọn kò ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà. Sibẹ Ọlọrun ń bọ́ wọn. Mélòó-mélòó ni ẹ fi sàn ju àwọn ẹyẹ lọ. Ta ni ninu yín tí ó lè páyà títí dé ibi pé yóo fi ẹsẹ̀ bàtà kan kún gíga rẹ̀? Nítorí náà, bí ẹ kò bá lè ṣe ohun tí ó kéré jùlọ, kí ló dé tí ẹ fi ń páyà nípa àwọn nǹkan yòókù? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu ọlá rẹ̀ kò wọ aṣọ tí ó dára tó wọn. Bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo fi aṣọ wọ̀ yín, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré yìí!
“Nítorí náà, ẹ̀yin ẹ má máa páyà kiri nítorí ohun tí ẹ óo jẹ. (Nítorí pé irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn alaigbagbọ ayé yìí ń dààmú kiri sí.) Baba yín sá mọ̀ pé ẹ nílò wọn. Ṣugbọn kí ẹ máa kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni yóo fun yín pẹlu.
“Ẹ má bẹ̀rù mọ́, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fun yín ní ìjọba rẹ̀. Ẹ ta àwọn ohun tí ẹ ní, kí ẹ fi ṣe ìtọrẹ-àánú. Ẹ dá àpò fún ara yín tí kò ní gbó laelae; ẹ to ìṣúra tí ó dájú jọ sí ọ̀run, níbi tí olè kò lè súnmọ́, tí kòkòrò kò sì lè ba nǹkan jẹ́. Nítorí níbi tí ìṣúra yín bá wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín náà yóo wà.
“Ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, kí ẹ di ara yín ní àmùrè, kí àtùpà yín wà ní títàn. Kí ẹ dàbí àwọn tí ó ń retí oluwa wọn láti pada ti ibi igbeyawo dé. Nígbà tí ó bá dé, tí ó bá kanlẹ̀kùn, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yóo ṣí ìlẹ̀kùn fún un. Àwọn ẹrú tí oluwa wọn bá dé, tí ó bá wọn, tí wọn ń ṣọ́nà, ṣe oríire. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo di ara rẹ̀ ní àmùrè, yóo fi wọ́n jókòó lórí tabili, yóo wá gbé oúnjẹ ka iwájú wọn. Bí ó bá dé ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tí ó bá wọn bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe oríire. Kí ẹ mọ èyí pé bí ó bá jẹ́ pé baálé ilé mọ àkókò tí olè yóo dé, kò ní fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ kí olè kó o. Ẹ̀yin náà, ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní àkókò tí ẹ kò nírètí ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.”
Peteru wá bi Jesu pé, “Oluwa, àwa ni o pa òwe yìí fún tabi fún gbogbo eniyan?”
Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò. Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ṣe oríire tí oluwa rẹ̀ bá bá a tí ó ń ṣe bí wọ́n ti rán an nígbà tí ó bá dé. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé oluwa rẹ̀ yóo fi ṣe ọ̀gá lórí gbogbo nǹkan tí ó ní. Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó, ní ọjọ́ tí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà kò retí, ati ní àkókò tí kò rò tẹ́lẹ̀ ni oluwa rẹ̀ yóo dé, yóo kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, yóo sì fún un ní ìpín pẹlu àwọn alaiṣootọ.
“Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ. Ṣugbọn èyí tí kò bá mọ̀, tí ó bá tilẹ̀ ṣe ohun tí ó fi yẹ kí ó jìyà, ìyà díẹ̀ ni yóo jẹ. Nítorí ẹni tí a bá fún ní nǹkan pupọ, nǹkan pupọ ni a óo retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí a bá sì fi nǹkan pupọ ṣọ́, nǹkan pupọ ni a óo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
“Iná ni mo wá sọ sí ayé. Ìbá ti dùn tó bí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jó! Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Ara mi kò lè balẹ̀ títí yóo fi kọjá. Ẹ má ṣe rò pé alaafia ni mo mú wá sí ayé. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ará! Mò ń sọ fun yín, ìyapa ni mo mú wá. Láti ìgbà yìí, ẹni marun-un yóo wà ninu ilé kan, àwọn mẹta yóo lòdì sí àwọn meji; àwọn meji yóo lòdì sí àwọn mẹta. Baba yóo lòdì sí ọmọ, ọmọ yóo lòdì sí baba. Ìyá yóo lòdì sí ọmọ rẹ̀ obinrin, ọmọbinrin yóo lòdì sí ìyá rẹ̀. Ìyakọ yóo lòdì sí iyawo ilé, iyawo ilé yóo lòdì sì ìyakọ rẹ̀.”
Jesu tún sọ fún àwọn eniyan pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i tí òjò ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, ẹ óo sọ pé, ‘Òjò yóo rọ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí. Bí atẹ́gùn bá fẹ́ wá láti gúsù, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ooru yóo mú,’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí. Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ mọ àmì ilẹ̀ ati ti ojú sánmà, ṣugbọn ẹ kò mọ àmì àkókò yìí!
“Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà? Bí o bá ń bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ lọ sí kóòtù, gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹlu rẹ̀ bí ẹ ti ń lọ lọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́. Onídàájọ́ yóo bá fi ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ni ọlọ́pàá yóo bá tì ọ́ mọ́lé. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé, o kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí o óo fi san gbogbo gbèsè tí o jẹ, láìku kọbọ!”