LEFITIKU 22:1-16

LEFITIKU 22:1-16 YCE

OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ pé, kí wọ́n máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo àwọn nǹkan mímọ́ tí àwọn eniyan Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLUWA. Bí èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ wọn bá súnmọ́ àwọn nǹkan mímọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí àwọn eniyan Israẹli ti yà sí mímọ́ fún OLUWA; nígbà tí ó wà ní ipò àìmọ́, a óo mú ẹni náà kúrò lọ́dọ̀ mi. Èmi ni OLUWA. “Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀, tabi ẹni tí ó bá fara kan èyíkéyìí ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri, èyí tí ó lè sọ eniyan di aláìmọ́, tabi ẹnikẹ́ni tí ó lè kó àìmọ́ bá eniyan, ohun yòówù tí àìmọ́ rẹ̀ lè jẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá wọ̀, yóo di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà nítorí oúnjẹ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́. Alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrara rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú bá pa; kí ó má baà fi òkú ẹran yìí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA. “Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́. “Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn. Ṣugbọn bí alufaa bá fi owó ra ẹrú fún ara rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà. Àwọn ọmọ tí ẹrú náà bá sì bí ninu ilé alufaa náà lè jẹ ninu oúnjẹ náà pẹlu. Bí ọmọbinrin alufaa kan bá fẹ́ àjèjì, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n bá fi rúbọ. Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá jẹ ohun mímọ́ kan ní ìjẹkújẹ yóo san án pada fún alufaa pẹlu ìdámárùn-ún rẹ̀. Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n fi ń rúbọ sí OLUWA di aláìmọ́. Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”