LEFITIKU 20

20
Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn
1OLUWA sọ fún Mose 2pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn ati àwọn àlejò, tí wọn ń ṣe àtìpó ní ààrin wọn tí ó bá fi èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, pípa ni kí wọ́n pa á; kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. 3Èmi gan-an yóo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó ti fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, ó sì ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ó ti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. 4Bí àwọn eniyan tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà bá mójú fo ẹni tí ó bá fi ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, tí wọn kò pa á, 5nígbà náà ni èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, n óo sì yọ wọ́n kúrò lára àwọn eniyan wọn, ati òun, ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jọ ń bọ oriṣa Moleki.
6“Bí ẹnìkan bá ń lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, tabi àwọn oṣó, tí ó sì ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, n óo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. 7Nítorí náà, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. 8Ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn. Èmi ni OLUWA tí ó sọ yín di mímọ́.
9“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀ nítorí pé ó ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀.#Eks 21:17; Mat 15:4; Mak 7:10.
10“Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀ ati obinrin tí ó bá lòpọ̀.#Eks 20:14; Lef 18:20; Diut 5:18. 11Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, ó dójúti baba rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.#Lef 18:18; Diut 22:30; 27:20 12Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya ọmọ rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji; wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ láàrin ẹbí, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn. 13Bí ọkunrin kan bá bá ọkunrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ bí a ti ń bá obinrin lòpọ̀, àwọn mejeeji ti ṣe ohun ìríra; pípa ni kí wọ́n pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.#Lef 18:22. 14Bí ẹnìkan bá fẹ́ iyawo, tí ó sì tún fẹ́ ìyá iyawo náà pẹlu, ìwà burúkú ni; sísun ni kí wọ́n sun wọ́n níná, ati ọkunrin ati àwọn obinrin mejeeji, kí ìwà burúkú má baà wà láàrin yín.#Lef 18:17; Diut 27:23 15Bí ọkunrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà. 16Bí obinrin bá tọ ẹranko lọ, tí ó sì tẹ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún un láti bá a lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.#Eks 22:19; Lef 18:23; Diut 27:21
17“Bí ọkunrin kan bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ baba rẹ̀ tabi ọmọ ìyá rẹ̀, tí wọ́n sì rí ìhòòhò ara wọn, ohun ìtìjú ni; lílé ni kí wọ́n lé wọn jáde kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn, nítorí pé ó ti bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀. Orí rẹ̀ ni yóo sì fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.#Lef 18:9; Diut 27:22 18Bí ọkunrin kan bá bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí obinrin yìí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, lílé ni kí wọ́n lé àwọn mejeeji kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn.#Lef 18:19.
19“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ, tabi arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ìwà ìbàjẹ́ ni láàrin ẹbí. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 20Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ.#Lef 18:12-14. 21Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ.#Lef 18:16.
22“Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ kíyèsí gbogbo àwọn ìlànà mi ati àwọn òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ tí mò ń ko yín lọ má baà tì yín jáde. 23Ẹ kò sì gbọdọ̀ kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo lé jáde fun yín, nítorí pé tìtorí gbogbo ohun tí wọn ń ṣe wọnyi ni mo fi kórìíra wọn. 24Ṣugbọn mo ti ṣèlérí fun yín pé, ẹ̀yin ni ẹ ó jogún ilẹ̀ wọn, n óo fi ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, tí ó sì ń ṣàn fún wàrà ati oyin fun yín, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo eniyan. 25Nítorí náà, ẹ níláti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹran tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́; ati láàrin àwọn ẹyẹ tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹyẹ tabi ẹranko kankan tabi àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri lórí ilẹ̀, tí mo ti yà sọ́tọ̀ fun yín pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́. 26Ẹ níláti jẹ́ mímọ́ fún mi, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA, mo sì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn eniyan kí ẹ lè máa jẹ́ tèmi.
27“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tabi oṣó, pípa ni kí ẹ pa á; ẹ sọ wọ́n ní òkúta pa ni, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì wà lórí ara wọn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LEFITIKU 20: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀