JOṢUA 8

8
Gbígbà ati Pípa Ìlú Ai Run
1OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ kí o lọ sí ìlú Ai. Wò ó! Mo ti fi ọba Ai, ati àwọn eniyan rẹ̀, ìlú rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. 2Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”
3Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́. 4Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀. 5Èmi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu mi nìkan ni a óo wọ ìlú náà. Nígbà tí wọ́n bá jáde sí wa láti bá wa jà bí i ti àkọ́kọ́, a óo sá fún wọn. 6Wọn yóo máa lé wa lọ títí tí a óo fi tàn wọ́n jáde kúrò ninu ìlú, nítorí wọn yóo ṣe bí à ń sálọ fún wọn bíi ti àkọ́kọ́ ni; nítorí náà ni a óo ṣe sá fún wọn. 7Ẹ̀yin ẹ dìde níbi tí ẹ farapamọ́ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yóo fi lé yín lọ́wọ́. 8Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà tán, ẹ ti iná bọ̀ ọ́, kí ẹ sì ṣe bí àṣẹ OLUWA. Ó jẹ́ àṣẹ tí mo pa fun yín.” 9Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà.
10Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn eniyan náà jọ. Òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli ṣáájú wọn, wọ́n lọ sí Ai. 11Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá a lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìlú Ai, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí apá ìhà àríwá ìlú náà, odò kan ni ó wà láàrin wọn ati ìlú Ai. 12Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai. 13Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi àwọn ọmọ ogun wọn sí ipò, àwọn tí wọn yóo gbógun ti ìlú gan-an wà ní apá ìhà àríwá ìlú, àwọn tí wọn yóo wà lẹ́yìn wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ṣugbọn Joṣua alára wà ní àfonífojì ní gbogbo òru ọjọ́ náà. 14Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú. 15Joṣua ati gbogbo ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá ṣe bí ẹni pé àwọn ará Ai ti ṣẹgun àwọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ. 16Àwọn ará Ai bá pe gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ìlú jọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. Bí wọ́n ti ń lé Joṣua lọ ni wọ́n ń jìnnà sí ìlú. 17Kò sì sí ẹyọ ọkunrin kan tí ó kù ní Ai ati Bẹtẹli tí kò jáde láti lépa àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n fi ìlẹ̀kùn ẹnubodè sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n ń lé àwọn ọmọ Israẹli lọ.
18OLUWA sọ fun Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ sí ọ̀kánkán Ai, nítorí n óo fi lé ọ lọ́wọ́.” Joṣua bá na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀kánkán ìlú náà. 19Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i. 20Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn. 21Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai. 22Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ninu ìlú náà jáde sí wọn, àwọn ará Ai sì wà ní agbede meji àwọn ọmọ Israẹli, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ keji. Àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n ní ìpakúpa títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan. 23Ṣugbọn wọ́n mú ọba Ai láàyè, wọ́n sì mú un tọ Joṣua wá.
24Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata. 25Gbogbo àwọn ará Ai tí wọ́n pa ní ọjọ́ náà, ati ọkunrin, ati obinrin, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaafa (12,000). 26Nítorí pé ọwọ́ tí Joṣua fi na ọ̀kọ̀ sókè, kò gbé e sílẹ̀ títí tí wọ́n fi pa gbogbo àwọn ará Ai tán. 27Àfi ẹran ọ̀sìn ati dúkìá ìlú náà ni àwọn ọmọ Israẹli kó ní ìkógun gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua. 28Joṣua dáná sun ìlú Ai, ó sì sọ ọ́ di òkítì àlàpà títí di òní olónìí. 29Ó so ọba Ai kọ́ sórí igi kan títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọn já òkú rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta jọ lé e lórí, òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.
Joṣua Ka Òfin ní Òkè Ebali
30Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli ní orí òkè Ebali, 31bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli ati gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sí inú ìwé òfin Mose pé, “Pẹpẹ tí wọ́n fi òkúta tí wọn kò gbẹ́ kọ́, tí ẹnikẹ́ni kò gbé ohun èlò irin sókè láti gbẹ́ òkúta rẹ̀.” Wọ́n rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA lórí rẹ̀.#Eks 20:25 32Joṣua mú òfin tí Mose kọ tẹ́lẹ̀, ó dà á kọ sórí àwọn òkúta náà lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.#Diut 27:2-8 33Gbogbo Israẹli, ati onílé, ati àlejò, gbogbo àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, ati àwọn aṣiwaju dúró ní òdìkejì Àpótí Majẹmu OLUWA, níwájú àwọn alufaa, ọmọ Lefi, tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu náà. Ìdajì wọn dúró níwájú òkè Ebali bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. 34Lẹ́yìn náà Joṣua ka gbogbo òfin náà sókè ati ibukun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. 35Kò sí ohun tí Mose pa láṣẹ tí Joṣua kò kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àlejò tí wọ́n wà ní ààrin wọn.#Diut 11:29; 27:11-14

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀