JOṢUA 10
10
Wọ́n Ṣẹgun Àwọn Ará Amori
1Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn, 2ẹ̀rù bà á gidigidi, nítorí pé ìlú ńlá ni ìlú Gibeoni bí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọba aládé. Gibeoni tóbi ju ìlú Ai lọ, akọni sì ni gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀. 3Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé, 4“Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí á kọlu Gibeoni, nítorí pé ó ti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia.” 5Nígbà náà ni àwọn ọba Amori maraarun, ọba Jerusalẹmu, ti Heburoni, ti Jarimutu, ti Lakiṣi, ati ti Egiloni parapọ̀, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Wọ́n lọ dó ti Gibeoni, wọ́n sì ń bá a jagun.
6Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.”
7Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni. 8OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.” 9Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali. 10OLUWA mú kí ìpayà bá àwọn ará Amori, nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Wọ́n lé wọn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, wọ́n sì pa wọ́n títí dé Aseka ati Makeda. 11Bí wọ́n sì ti ń sá lọ fún àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, OLUWA mú kí àwọn òkúta ńláńlá máa bọ́ lù wọ́n láti ojú ọ̀run, títí tí wọ́n fi dé Aseka, wọ́n sì kú. Àwọn tí òkúta ńláńlá wọnyi pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lọ.
12Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní,
“Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni.
Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.”
13Oòrùn bá dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró jẹ́ẹ́, títí tí àwọn ọmọ Israẹli fi gbẹ̀san tán lára àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n kọ ọ́ sinu ìwé Jaṣari pé, oòrùn dúró ní agbede meji ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún bí odidi ọjọ́ kan. 14Irú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ kò wáyé rí ṣáájú ìgbà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni, láti ìgbà náà, kò sì tíì tún ṣẹlẹ̀, pé kí OLUWA gba ọ̀rọ̀ sí eniyan lẹ́nu, èyí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé, OLUWA jà fún Israẹli.#2 Sam 1:18; Sir 46:4-6.
15Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí àgọ́ wọn ní Giligali.
Joṣua Fi Ogun Kó Àwọn Ọba Amori Maraarun
16Àwọn ọba maraarun sá, wọ́n sì fi ara pamọ́ sinu ihò tí ó wà ní Makeda. 17Àwọn kan wá sọ fún Joṣua pé wọ́n ti rí àwọn ọba maraarun ní ibi tí wọ́n fi ara pamọ́ sí ní Makeda. 18Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Ẹ yí òkúta ńláńlá dí ẹnu ihò náà kí ẹ sì fi àwọn eniyan sibẹ, láti máa ṣọ́ wọn. 19Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ dúró níbẹ̀, ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín lọ, kí ẹ máa pa wọ́n láti ẹ̀yìn. Ẹ má jẹ́ kí wọ́n pada wọnú ìlú wọn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ti fi wọ́n le yín lọ́wọ́.” 20Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán, 21gbogbo àwọn eniyan pada sọ́dọ̀ Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Makeda láìsí ewu.
Kò sì sí ẹni tí ó sọ ìsọkúsọ sí àwọn ọmọ Israẹli.
22Lẹ́yìn náà, Joṣua ní, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì kó àwọn ọba maraarun náà wá fún mi.” 23Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni. 24Nígbà tí wọ́n kó àwọn ọba náà dé ọ̀dọ̀ Joṣua, ó pe gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli jọ, ó sọ fún àwọn ọ̀gágun tí wọ́n bá a lọ sí ojú ogun pé, “Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín tẹ ọrùn àwọn ọba wọnyi.” Wọ́n bá súnmọ́ Joṣua, wọ́n sì tẹ àwọn ọba náà lọ́rùn mọ́lẹ̀. 25Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.” 26Lẹ́yìn náà, Joṣua fi idà pa wọ́n, ó so wọ́n kọ́ orí igi marun-un, wọ́n sì wà lórí àwọn igi náà títí di ìrọ̀lẹ́. 27Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọ́n já òkú wọn lulẹ̀ kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu ihò tí wọ́n sápamọ́ sí, wọ́n sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà. Ó wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.
Joṣua Tún Gba Àwọn Ìlú Amori Mìíràn Sí i
28Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda.
29Joṣua gbéra ní Makeda, ó kọjá lọ sí Libina pẹlu gbogbo Israẹli láti gbógun ti Libina. 30OLUWA sì fi ìlú Libina ati ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n fi idà pa wọ́n, wọn kò ṣẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu wọn. Bí ó ti ṣe ọba Jẹriko, náà ló ṣe sí ọba ìlú náà.
31Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra láti Libina lọ sí Lakiṣi. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì bá a jagun. 32OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina.
33Horamu ọba Geseri wá láti ran àwọn ará ìlú Lakiṣi lọ́wọ́, Joṣua gbógun tì í, ó sì pa òun ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ láìku ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.
34Joṣua kúrò ní Lakiṣi, ó lọ sí Egiloni pẹlu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dó ti Egiloni, wọ́n sì bá a jagun. 35Wọ́n gba ìlú náà ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ patapata gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí àwọn ará Lakiṣi.
36Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Egiloni lọ sí Heburoni, wọ́n sì gbógun tì í. 37Wọ́n gba ìlú Heburoni, wọ́n sì fi idà pa ọba ìlú náà ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ láìku ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ìlú Egiloni tí wọn parun láìku ẹnìkan.
38Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí Debiri, wọ́n sì gbógun tì í. 39Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n mú ọba ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ìlú kéékèèké agbègbè rẹ̀ pẹlu. Wọ́n fi idà pa ọba wọn ati gbogbo àwọn ará ìlú náà. Gbogbo wọn ni wọ́n pa láìku ẹnìkan. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Heburoni, ati Libina ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe sí Debiri ati ọba rẹ̀.
40Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un. 41Joṣua ṣẹgun gbogbo wọn láti Kadeṣi Banea títí dé Gasa ati gbogbo agbègbè Goṣeni títí dé Gibeoni. 42Joṣua mú gbogbo àwọn ọba wọnyi, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nítorí pé OLUWA Ọlọrun jà fún Israẹli. 43Lẹ́yìn náà, Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pada sí àgọ́ wọn, ní Giligali.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOṢUA 10: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010