JONA 3

3
Jona Gbọ́ràn sí OLUWA Lẹ́nu
1OLUWA tún bá Jona sọ̀rọ̀ nígbà keji, ó ní: 2“Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kí o sì kéde iṣẹ́ tí mo rán ọ fún gbogbo eniyan ibẹ̀.” 3Jona bá dìde, ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. Ninefe jẹ́ ìlú tí ó tóbi, ó gbà tó ìrìn ọjọ́ mẹta láti la ìlú náà já. 4Jona rin ìlú náà fún odidi ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Níwọ̀n ogoji ọjọ́ sí i, Ninefe óo parun.”
5Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.#Mat 12:41; Luk 11:32
6Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọba Ninefe ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù oyè sílẹ̀, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó ninu eérú. 7Ó bá ní kí wọn kéde fún àwọn ará Ninefe, pé, “Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ pàṣẹ pé, eniyan tabi ẹranko, tabi ẹran ọ̀sìn kankan kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ, wọn kò sì gbọdọ̀ mu. 8Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì. 9A kì í mọ̀, bóyá Ọlọrun lè yí ọkàn rẹ̀ pada, kí ó má jẹ wá níyà mọ́. Bóyá yóo tilẹ̀ dá ibinu rẹ̀ dúró, kò sì ní pa wá run.”
10Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti pa ìwà burúkú wọn tì, Ọlọrun náà bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, kò sì jẹ wọ́n níyà mọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JONA 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀