JONA 2:1-6

JONA 2:1-6 YCE

Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà, ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi. Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun, omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀; ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi. Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ; báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’ Omi bò mí mọ́lẹ̀, ibú omi yí mi ká, koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí. Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun, àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi, o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.