JOBU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Jobu jẹ́ ìtàn ọkunrin rere kan tí oríṣìíríṣìí ìṣòro dé bá–ó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ ati ohun ìní rẹ̀, oówo burúkú tún dà bò ó. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí fi ewì ṣe àgbékalẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pataki láàrin Jobu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lórí àwọn àjálù tí ó dé bá Jobu. Àjọṣe láàrin Ọlọrun ati àwọn eniyan ni kókó tí wọ́n tẹnumọ́ jù ninu ọ̀rọ̀ wọn; níkẹyìn Ọlọrun fara han Jobu.
Àwọn ọ̀rẹ́ Jobu fi ojú ìdájọ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wo àjálù tí ó dé bá Jobu. Igbagbọ tiwọn ni pé Ọlọrun a máa san ẹ̀san ohun tí eniyan bá ṣe fún un, ìbáà jẹ́ burúkú tabi ire, ati pé àjálù tí ó dé bá Jobu gbọdọ̀ jẹ́ ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ní ti Jobu, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀; irú àjálù burúkú yìí kò tọ́ sí i, nítorí ẹni rere ati olódodo eniyan bíi tirẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Pẹlu ẹ̀mí ìgboyà, Jobu bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ìdí tí ó fi lè jẹ́ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí òun. Ninu gbogbo ìṣòro yìí, Jobu di igbagbọ rẹ̀ mú ṣinṣin, ṣugbọn ó fẹ́ kí Ọlọrun dá òun láre kí ó sì jẹ́ kí òun gba ògo òun pada gẹ́gẹ́ bí ẹni rere.
Ọlọrun kò dáhùn sí gbogbo ìbéèrè Jobu, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fi ewì sọ títóbi agbára ńlá rẹ̀ ati ọgbọ́n rẹ̀ fún Jobu. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jobu fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbé Ọlọrun ga gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ati ẹni ńlá, ó sì tọrọ ìdáríjì fún gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó fi ibinu sọ.
Ìparí ọ̀rọ̀ náà ni àkọsílẹ̀ bí Jobu ṣe pada bọ̀ sípò rẹ̀ àtijọ́ tí ó tún ní ọrọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Jobu nìkan ni ó mọ̀ dájú pé Ọlọrun tóbi ju bí àwọn eniyan ṣe ń fi ojú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wò ó lọ. Ọlọrun jẹ àwọn ọ̀rẹ́ Jobu níyà nítorí pé wọn kò mọ ìdí ìnira tí ó dé bá Jobu.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí náà
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1–2:13
Jobu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ 3:1–31:40
a. Ìráhùn Jobu 3:1-26
b. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àkọ́kọ́ 4:1–14:22
d. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹẹkeji 15:1–21:34
e. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹẹkẹta 22:1–27:23
ẹ. Yiyin ọgbọ́n 28:1-28
f. Ọ̀rọ̀ tí Jobu sọ kẹ́yìn 29:1–31:40
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Elihu sọ 32:1–37:24
Èsì tí OLUWA fún Jobu 38:1–42:6
Ọ̀rọ̀ ìparí 42:7-17

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀