JOBU 20

20
1Sofari, ará Naama bá dáhùn pé,
2“Lọ́kàn mi, mo fẹ́ fèsì sí ọ̀rọ̀ rẹ,
ara sì ń wá mi, bí ẹni pé kí n dá ọ lóhùn.
3Mo gbọ́ èébú tí o bú mi,
mo sì mọ irú èsì tí ó yẹ kí n fọ̀.
4Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé,
5pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn,
tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni.
6Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run,
tí orí rẹ̀ kan sánmà,
7yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀,
àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’
8Yóo parẹ́ bí àlá,
yóo sì di àwátì,
yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru.#Ọgb 5:14
9Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́,
ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo.
10Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní,
wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada.
11Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára,
sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀.
12Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀,
tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀,
13bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde,
tí ó pa ẹnu mọ́,
14sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú,
ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.
15Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde;
Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀.
16Yóo mu oró ejò,
ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á.
17Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò.
18Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀.
19Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀,
ó sì ti pa wọ́n tì sí apákan
ó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́.
20Nítorí pé oníwọ̀ra ni,
tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan,
kò lè pa á mọ́ra.
21Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù,
nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.
22Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,
ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.
23Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,
ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,
tí yóo sì dà lé e lórí.
24Bí ó bá ti ń sá fún idà,
bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.#Ọgb 5:17-23
25Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀,
tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀,
ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.
26Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é,
iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun,
ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.
27Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn,
ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́.
28Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ,
àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù.
29Bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ibi yóo rí.
Ọlọrun ni ó ti yàn án bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ wá.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 20: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀