JOBU 18
18
1Bilidadi ará Ṣuha bá tún dáhùn pé,
2“Ìgbàwo ni o óo sinmi ẹjọ́ tí ò ń tò yìí?
Ohun tí a tí ń bá ọ sọ ni kí o gbé yẹ̀wò,
kí á lè sọ èyí tí a tún fẹ́ sọ.
3Kí ló dé tí o fi kà wá sí ẹranko,
tí a di òmùgọ̀ lójú rẹ?
4Ìwọ tí o faraya nítorí inú ń bí ọ,
ṣé kí á sá kúrò láyé nítorí rẹ ni,
tabi kí á ṣí àwọn àpáta nípò pada?
5“Nítòótọ́, a ti pa fìtílà ẹni ibi,
ahọ́n iná rẹ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.
6Inú àgọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn,
a sì ti pa àtùpà ìgbèrí rẹ̀.
7Agbára rẹ̀ ti dín kù,
ète rẹ̀ sì gbé e ṣubú.
8Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n,
ó ń rìn lórí ọ̀fìn.
9Tàkúté ti mú un ní gìgísẹ̀,
ó ti kó sinu pańpẹ́.
10A dẹ okùn sílẹ̀ fún un,
a sì dẹ pańpẹ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀.
11“Ìbẹ̀rù yí i ká,
wọ́n ń lé e kiri.
12Ebi pa agbára mọ́ ọn ninu,
ìṣòro sì ti ṣetán láti gbé e ṣubú.
13Àìsàn burúkú jẹ awọ ara rẹ̀,
àkọ́bí ikú jẹ ẹ́ tọwọ́ tẹsẹ̀.
14A fipá wọ́ ọ kúrò ninu àgọ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,
a sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ọba Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀.#18:14 Ikú ni a dà pè ní Ọba Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ .
15Àgọ́ rẹ̀ kún fún àwọn tí kì í ṣe tirẹ̀,
imí-ọjọ́ fọ́nká sí gbogbo ibùgbé rẹ̀.
16Gbòǹgbò rẹ̀ gbẹ nísàlẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ sì gbẹ lókè.
17Ó di ẹni ìgbàgbé lórílẹ̀ ayé,
bẹ́ẹ̀ ni a kò gbórúkọ rẹ̀ mọ́ ní ìgboro.
18Wọ́n tì í láti inú ìmọ́lẹ̀ sinu òkùnkùn,
wọ́n lé e kúrò láyé.
19Kò lọ́mọ, kò lọ́mọ ọmọ,
kò sì sí ẹni tí yóo rọ́pò rẹ̀ ní ibùgbé rẹ̀,
láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
20Ẹnu yóo ya àwọn ará ìwọ̀ oòrùn,
ìwárìrì yóo sì mú àwọn ará ìlà oòrùn,
nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.
21Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé ẹni ibi yóo rí,
àní, ilé ẹni tí kò mọ Ọlọrun.”#Job 21:17
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 18: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010