“Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí, tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi. Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n, ẹ kò sàn jù mí lọ. Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́. Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi, ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn. Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni, à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n! Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi, kí ẹ sì fetísí àròyé mi. Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni, kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀? Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni? Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀? Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò? Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan? Dájúdájú, yóo ba yín wí, bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀. Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín, jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín. Àwọn òwe yín kò wúlò, àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Kà JOBU 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 13:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò