JOHANU 9:1-12

JOHANU 9:1-12 YCE

Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olùkọ́ni, ta ni ó dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yìí ni, tabi àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n fi bí i ní afọ́jú?” Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni. Dandan ni fún mi kí n ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi ní ojúmọmọ, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ ṣú ná, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè ṣiṣẹ́. Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi po amọ̀, ó bá fi lẹ ojú ọkunrin náà. Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran. Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?” Àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni!” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó jọ ọ́ ni.” Ọkunrin náà ni, “Èmi gan-an ni.” Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.” Wọ́n bi í pé, “Níbo ni ọkunrin náà wà?” Ó dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.”

Àwọn fídíò fún JOHANU 9:1-12