JOHANU 8:31-51

JOHANU 8:31-51 YCE

Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́; ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.” Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ẹrú kì í gbé inú ilé títí, ọmọ níí gbé inú ilé títí. Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ óo di òmìnira nítòótọ́. Mo mọ̀ pé ìran Abrahamu ni yín, sibẹ ẹ̀ ń wá ọ̀nà láti pa mí, nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè ninu yín. Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba mi ni mò ń sọ, ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́ lọ́dọ̀ baba yín ni ẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n sọ fún un pé, “Abrahamu ni baba wa.” Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọ Abrahamu ni yín, irú ohun tí Abrahamu ṣe ni ẹ̀ bá máa ṣe. Ṣugbọn ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, bẹ́ẹ̀ sì ni òtítọ́ tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọrun ni mo sọ fun yín. Abrahamu kò hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Irú ohun tí baba yín ṣe ni ẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í ṣe ọmọ àlè, baba kan ni a ní, òun náà sì ni Ọlọrun.” Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi. Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi. Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́. Ṣugbọn nítorí pe òtítọ́ ni mò ń sọ, ẹ kò gbà mí gbọ́. Ta ni ninu yín tí ó ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ rí? Bí mo bá ń sọ òtítọ́, kí ló dé tí ẹ kò fi gbà mí gbọ́? Ẹni tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí tí ẹ kò fi gbọ́ ni èyí, nítorí ẹ kì í ṣe ẹni Ọlọrun.” Àwọn Juu sọ fún un pé, “A kúkú ti sọ pé ará Samaria ni ọ́, ati pé o ní ẹ̀mí èṣù!” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù rárá! Èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ṣugbọn ẹ̀yin ń bu ẹ̀tẹ́ lù mí. Èmi kò wá ògo ti ara mi, ẹnìkan wà tí ó ń wá ògo mi, òun ni ó ń ṣe ìdájọ́. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní kú laelae.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ