Àwọn amòfin ati àwọn Farisi mú obinrin kan wá, tí wọ́n ká mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè. Wọ́n ní kí ó dúró láàrin wọn; wọ́n wá sọ fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, a ká obinrin yìí mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè, a ká a mọ́ ọn gan-an ni! Ninu Òfin wa Mose pàṣẹ pé kí á sọ irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní òkúta pa. Kí ni ìwọ wí?” Wọ́n sọ èyí láti fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu ni kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kàn án. Jesu bá bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀. Bí wọ́n ti dúró tí wọ́n tún ń bi í, ó gbé ojú sókè ní ìjókòó tí ó wà, ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí kò bá ní ẹ̀ṣẹ̀ ninu yín ni kí ó kọ́ sọ ọ́ ní òkúta.” Ó bá tún bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbààgbà ni wọ́n kọ́ lọ. Gbogbo wọ́n bá túká pátá láìku ẹnìkan. Ó wá ku obinrin yìí nìkan níbi tí ó dúró sí. Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó bi obinrin náà pé, “Obinrin, àwọn dà? Ẹnìkan ninu wọn kò dá ọ lẹ́bi?” Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”]
Kà JOHANU 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 8:3-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò