Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá; nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.” Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae. Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ̀yin ti rí mi, sibẹ ẹ kò gbàgbọ́. Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù; nítorí pé mo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bíkòṣe láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Èyí ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́, pé kí n má ṣe sọ ẹnikẹ́ni nù ninu àwọn tí ó fi fún mi, ṣugbọn kí n jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”
Kà JOHANU 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 6:32-40
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò