JOHANU 4:9-14

JOHANU 4:9-14 YCE

Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.) Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, o kò ní ohun tí o lè fi fa omi, kànga yìí sì jìn, níbo ni ìwọ óo ti mú omi ìyè wá? Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.”

Àwọn fídíò fún JOHANU 4:9-14