JOHANU 4:1-30

JOHANU 4:1-30 YCE

Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ ju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu lọ; ati pé Jesu ń ṣe ìrìbọmi fún ọpọlọpọ eniyan ju Johanu lọ. Ṣugbọn ṣá, kì í ṣe Jesu fúnrarẹ̀ ni ó ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni. Nígbà tí Jesu mọ̀ pé àwọn Farisi ti gbọ́ ìròyìn yìí, ó kúrò ní Judia, ó tún pada lọ sí Galili. Ó níláti gba ààrin ilẹ̀ Samaria kọjá. Ó dé ìlú Samaria kan tí ń jẹ́ Sikari, lẹ́bàá ilẹ̀ tí Jakọbu fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. Kànga kan tí ó ní omi wà níbẹ̀, tí Jakọbu gbẹ́ nígbà ayé rẹ. Jesu jókòó létí kànga náà ní nǹkan bí agogo mejila ọ̀sán, àárẹ̀ ti mú un nítorí ìrìn àjò tí ó rìn. Obinrin kan ará Samaria wá pọn omi. Jesu wí fún un pé, “Fún mi ní omi mu.” (Ní àkókò yìí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ ra oúnjẹ ninu ìlú.) Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.) Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, o kò ní ohun tí o lè fi fa omi, kànga yìí sì jìn, níbo ni ìwọ óo ti mú omi ìyè wá? Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí kí òùngbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí n má baà tún wá pọn omi níhìn-ín mọ́.” Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.” Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ, nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́. Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.” Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, gbà mí gbọ́! Àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé, ati ní orí òkè yìí ni, ati ní Jerusalẹmu ni, kò ní sí ibi tí ẹ óo ti máa sin Baba mọ́. Ẹ̀yin ará Samaria kò mọ ẹni tí ẹ̀ ń sìn. Àwa Juu mọ ẹni tí à ń sìn, nítorí láti ọ̀dọ̀ wa ni ìgbàlà ti wá. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.” Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.” Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.” Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀? Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?” Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.

Àwọn fídíò fún JOHANU 4:1-30

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú JOHANU 4:1-30