JOHANU 3:3-6

JOHANU 3:3-6 YCE

Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.” Nikodemu bi í pé, “Báwo ni a ti ṣe lè tún ẹni tí ó ti di àgbàlagbà bí? Kò sá tún lè pada wọ inú ìyá rẹ̀ lẹẹkeji kí á wá tún un bí!” Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti ẹran-ara, ẹran-ara ni. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti Ẹ̀mí, ẹ̀mí ni.

Àwọn fídíò fún JOHANU 3:3-6