Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?”
Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!”
Ó wí fún wọn pé, “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ óo rí ẹja pa.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọn kò bá lè fa àwọ̀n mọ́, nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.
Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń bọ̀ ninu ọkọ̀, nítorí wọn kò jìnnà sí èbúté, wọn kò jù bí ìwọ̀n ọgọrun-un ìgbésẹ̀ lọ. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná eléèédú, wọ́n tún rí burẹdi. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú wá ninu ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.”
Nígbà náà ni Simoni Peteru gòkè, ó fa àwọ̀n sí èbúté. Àwọ̀n náà kún fún ẹja ńláńlá, mẹtalelaadọjọ. Ṣugbọn bí wọ́n ti pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò ya. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun.” Kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bi í pé, “Ta ni ọ́?” Wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni. Jesu wá, ó mú burẹdi, ó fi fún wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó fún wọn ní ẹja jẹ.
Èyí ni ó di ìgbà kẹta tí Jesu fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́yìn ajinde rẹ̀ ninu òkú.
Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jesu bi Simoni Peteru pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi ju àwọn wọnyi lọ?”
Peteru dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”
Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ aguntan mi.” Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?”
Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”
Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.” Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?”
Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”
Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, ò ń di ara rẹ ni àmùrè gírí, ò ń lọ sí ibi tí o bá fẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá di arúgbó, ìwọ yóo na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóo wọ aṣọ fún ọ, yóo fà ọ́ lọ sí ibi tí o kò fẹ́ lọ.” (Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”