Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà. Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”
Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.”
Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn. Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀. Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”
Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”
Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.” (Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”)
Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ó ní idà kan fà á yọ, ó bá ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó gé e létí ọ̀tún. Maliku ni orúkọ ẹrú náà. Jesu bá sọ fún Peteru pé, “Ti idà rẹ bọ inú àkọ̀. Àbí kí n má jẹ ìrora ńlá tí Baba ti yàn fún mi ni?”
Ni àwọn ọmọ-ogun ati ọ̀gágun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn Juu bá mú Jesu, wọ́n dè é, wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Anasi tíí ṣe baba iyawo Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà. Kayafa yìí ni ó fi ìmọ̀ràn fún àwọn Juu pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún gbogbo eniyan.
Ṣugbọn Simoni Peteru ń tẹ̀lé Jesu pẹlu ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn. Ọmọ-ẹ̀yìn keji yìí jẹ́ ẹni tí Olórí Alufaa mọ̀. Ṣugbọn Peteru dúró lóde lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn keji tí Olórí Alufaa mọ̀ jáde, ó bá mú Peteru wọ agbo-ilé. Nígbà náà ni ọmọge tí ó ń ṣọ́nà sọ fún Peteru pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkunrin yìí ni ọ́?”
Peteru dáhùn pé, “Rárá o!”
Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná.
Olórí Alufaa bi Jesu nípa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀. Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀. Kí ni ò ń bi mí sí? Bi àwọn tí ó ti gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn; wọ́n mọ ohun tí mo sọ.”
Bí ó ti sọ báyìí tán ni ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó dúró níbẹ̀ bá gbá Jesu létí, ó ní, “Olórí Alufaa ni o dá lóhùn bẹ́ẹ̀!”
Jesu dá a lóhùn pé, “Bí burúkú ni mo bá sọ, wí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí ayé gbọ́. Tí ó bá jẹ́ rere ni mo sọ, kí ló dé tí o fi lù mí?”