“Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi. Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná. Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà. Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.
Kà JOHANU 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 15:5-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò