“Èmi ni àjàrà tòótọ́. Baba mi ni àgbẹ̀ tí ń mójútó ọgbà àjàrà. Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ. Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín. Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi. Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná. Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà. Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi. Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀. “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín.
Kà JOHANU 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 15:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò