Ní ọjọ́ keji, ọpọlọpọ eniyan tí ó wá ṣe àjọ̀dún gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa ati ọba Israẹli.”
Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,
“Má bẹ̀rù mọ́, ọdọmọbinrin Sioni,
Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,
ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i.
Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí. Nítorí èyí ni àwọn eniyan ṣe lọ pàdé rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí. Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!”
Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”
Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ ní ayé yìí yóo pa á mọ́ títí di ìyè ainipẹkun. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.”
Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.”
Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.”
Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.”
Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín. Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde. Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.” Ó sọ èyí, ó fi ṣe àkàwé irú ikú tí yóo kú.
Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?”
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.”
Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́. Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé,
“Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́?
Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?”
Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé,
“Ojú wọn ti fọ́,
ọkàn wọn sì ti le;
kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,
kí òye má baà yé wọn.
Kí wọn má baà yipada,
kí n má baà wò wọ́n sàn.”
Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.
Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ; nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ.
Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹni tí ó bá rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò bá pa á mọ́, èmi kò ní dá a lẹ́jọ́, nítorí n kò wá sí ayé láti ṣe ìdájọ́, ṣugbọn mo wá láti gba aráyé là. Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, ó ní ohun tí yóo dá a lẹ́jọ́, ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ni yóo dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn. Nítorí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ti ara mi ni mò ń sọ, bíkòṣe ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́, tí ó ti fún mi ní àṣẹ ohun tí n óo sọ ati ohun tí n óo wí. Mo mọ̀ pé òfin rẹ̀ ń tọ́ni sí ìyè ainipẹkun. Nítorí náà, bí Baba ti sọ fún mi pé kí n wí, bẹ́ẹ̀ gan-an ni mò ń sọ.”