JOHANU 10

10
Jesu Fi Aguntan Ṣe Àkàwé
1“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni. 2Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́-aguntan. 3Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ. 4Nígbà tí gbogbo àwọn aguntan rẹ̀ bá jáde, a máa lọ níwájú wọn, àwọn aguntan a sì tẹ̀lé e nítorí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. 5Aguntan kò jẹ́ tẹ̀lé àlejò, sísá ni wọ́n máa ń sá fún un, nítorí wọn kò mọ ohùn àlejò.”
6Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn.
Jesu Ni Olùṣọ́-Aguntan Rere
7Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan. 8Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn. 9Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ. 10Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
11“Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. #Sir 18:13 12Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká, 13nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan. 14Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí, 15gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. #Mat 11:27; Luk 10:22 16Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan.
17“Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè. 18Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”
19Ìyapa tún bẹ́ sáàrin àwọn Juu nítorí ọ̀rọ̀ yìí. 20Ọpọlọpọ ninu wọn sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ ti dàrú. Kí ni ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí?”
21Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù lè la ojú afọ́jú?”
Àwọn Juu Kọ Jesu
22Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu, #1 Makab 4:36, 52-59; 2 Makab 1:18; 10:5 23Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili. 24Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.”
25Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi, 26ṣugbọn ẹ kò gbàgbọ́, nítorí ẹ kò sí ninu àwọn aguntan mi. 27Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi. 28Mo fún wọn ní ìyè ainipẹkun, wọn kò lè kú mọ́ laelae, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè já wọn gbà mọ́ mi lọ́wọ́. 29Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju ohun gbogbo lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè já a gbà mọ́ Baba mi lọ́wọ́. #Ọgb 3:1 30Ọ̀kan ni èmi ati Baba mi.”
31Àwọn Juu tún ṣa òkúta láti sọ lù ú. 32Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”
33Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.” #Lef 24:16
34Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’ #O. Daf 82:6 35Ìwé Mímọ́ kò ṣe é parẹ́. Bí Ọlọrun bá pe àwọn tí ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ní ọlọ́run, 36kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé? 37Bí n kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. 38Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.”
39Nígbà náà ni wọ́n tún ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ó jáde kúrò ní àrọ́wọ́tó wọn.
40Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀. #Joh 1:28 41Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.” 42Ọpọlọpọ eniyan bá gbà á gbọ́ níbẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOHANU 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

Àwọn fídíò fún JOHANU 10