JEREMAYA 52

52
Ìṣubú Jerusalẹmu
(2A. Ọba 24:18–25:7)
1Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀. 2Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe. 3Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀.
Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni. 4Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká. 5Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya. 6Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn mú ní ààrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́. 7Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani. 8Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀. 9Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un. 10Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila. 11Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú.#Isi 24:2 #Isi 33:21 #Isi 12:13
Wọ́n Wó Tẹmpili Lulẹ̀
(2A. Ọba 25:8-17)
12Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu. 13Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun. 14Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata. 15Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́. 16Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko.#1A. Ọba 9:8
17Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni. 18Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA. 19Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ. 20Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n. 21Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òpó náà ga ní igbọnwọ mejidinlogun, àyíká wọn jẹ́ igbọnwọ mejila, wọ́n nípọn, ní ìka mẹrin, wọ́n sì ní ihò ninu. 22Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká. 23Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.#1A. Ọba 7:15-47
Wọ́n Kó Àwọn Ará Juda ní Ìgbèkùn Lọ sí Babiloni
(2A. 8Oba 25:18-21, 27-30)
24Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta. 25Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro. 26Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila. 27Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.
Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn. 28Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu. 29Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu. 30Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600).
31Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé. 32Ó bá a sọ ọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga jùlọ, àní ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ. 33Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34Ọba Babiloni sì rí i pé òun ń pèsè gbogbo ohun tí ó nílò lojoojumọ fún un títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 52: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀