JEREMAYA 45
45
Ìlérí Ọlọrun fún Baruku
1Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya wolii sọ fún Baruku ọmọ Neraya nìyí, ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya, jọba ní Juda. Baruku ń kọ ohun tí Jeremaya ń sọ sílẹ̀ bí Jeremaya tí ń sọ̀rọ̀. 2Ó ní: “OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún ìwọ Baruku pé, 3ò ń sọ pé, o gbé, nítorí pé OLUWA ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora rẹ; àárẹ̀ mú ọ nítorí ìkérora rẹ, o kò sì ní ìsinmi.#2A. Ọba 24:1; 2Kron 36:5-7, Dan 1:1,2
4“Èmi ń wó ohun tí mo kọ́ lulẹ̀, mo sì ń tu ohun tí mo gbìn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ gbogbo ilẹ̀ náà rí. 5Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 45: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010