JEREMAYA 18:1-6

JEREMAYA 18:1-6 YCE

OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní: “Dìde, lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni óo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ.” Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò. Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.