Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.” Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.”
Kà ÀWỌN ADÁJỌ́ 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÀWỌN ADÁJỌ́ 6:13-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò