Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli.
Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu. Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́. Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ láti jagun, OLUWA á kẹ̀yìn sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti kìlọ̀ fún wọn tí ó sì búra fún wọn, ìdààmú a sì dé bá wọn.
Lẹ́yìn náà, OLUWA á gbé àwọn adájọ́ kan dìde, àwọn adájọ́ náà á sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà tí ń kó wọn ní nǹkan. Sibẹsibẹ, wọn kì í gbọ́ ti àwọn aṣiwaju wọn. Wọn a máa sá lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa káàkiri, wọn a sì máa bọ wọ́n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á yipada kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba wọn ń rìn. Àwọn baba wọn a máa pa òfin OLUWA mọ́, ṣugbọn ní tiwọn àwọn kì í pa á mọ́. Nígbàkúùgbà tí OLUWA bá gbé aṣiwaju kan dìde fún wọn, OLUWA a máa wà pẹlu aṣiwaju náà, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, ní àkókò aṣiwaju náà. Ìkérora àwọn ọmọ Israẹli a máa mú kí àánú wọn ṣe OLUWA, nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára. Ṣugbọn bí aṣiwaju yìí bá ti kú, kíá, wọn a tún ti yipada, wọn a sì tún ti máa ṣe ohun tí ó burú ju ohun tí àwọn baba wọn ti ṣe lọ. Wọn a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọ́n a máa bọ wọ́n, wọn a sì máa foríbalẹ̀ fún wọn. Wọn kì í sì í fi ìṣe wọn ati oríkunkun wọn sílẹ̀. Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi. Láti ìsinsìnyìí lọ n kò ní lé èyíkéyìí, ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù kí Joṣua tó kú, jáde fún wọn. Àwọn ni n óo lò láti wò ó bí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tọ ọ̀nà tí mo là sílẹ̀, bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe.” Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn.