Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú. Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ. Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí. Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù. Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀.
Kà JAKỌBU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JAKỌBU 1:19-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò