N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́, n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀; nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa, ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli, tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀, ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀. OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.” Ó sì di Olùgbàlà wọn. Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni, angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là. Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada. Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.
Kà AISAYA 63
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 63:7-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò