AISAYA 43:8-9

AISAYA 43:8-9 YCE

Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde, àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́, wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di. Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ, kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀. Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá; kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́, kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”