AISAYA 42:2-3

AISAYA 42:2-3 YCE

Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo, kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba. Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú, yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́.