Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé, tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ, mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́, mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’ Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ. N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́; ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú. Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán, wọn óo sì ṣègbé. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì, o kò ní rí wọn. Àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóo di òfo patapata. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.
Kà AISAYA 41
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 41:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò