AISAYA 40:9-31

AISAYA 40:9-31 YCE

Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni, kí o máa kéde ìyìn rere. Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu, ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere ké sókè má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú Juda pé, “Ẹ wo Ọlọrun yín.” Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso. Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn. Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun? Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run, Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé sinu òṣùnwọ̀n? Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n? Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA, ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye, ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́, tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀, tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án? Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi, ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n. Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè. Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun. Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀, wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n. Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé, tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀? Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe; tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bò tí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún? Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ, a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju; a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́, láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà. Ṣé ẹ kò tíì mọ̀? Ẹ kò sì tíì gbọ́? Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀, kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé: Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé, àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀. Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa, ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀. Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀, ó sọ àwọn olóyè ayé di asán. Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n, wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀; nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, tí wọ́n fi rọ bí ewéko, tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko. Ta ni ẹ óo wá fi mí wé, tí n óo sì dàbí rẹ̀? Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀. Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run, ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi? Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun, tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan, tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀. Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó, ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó, ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì. Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́? Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé, “OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí, Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.” Ṣé o kò tíì mọ̀, o kò sì tíì gbọ́ pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA, Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé. Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Àwámárìídìí ni òye rẹ̀. A máa fún aláàárẹ̀ ní okun. A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára. Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn, àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA yóo máa gba agbára kún agbára. Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì. Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn; wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú AISAYA 40:9-31